1 Peteru 4:16
1 Peter 4:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í, ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí.
1 Peter 4:16 in English
1 Peter 4:16 · Berean Standard Bible
But if you suffer as a Christian, do not be ashamed, but glorify God that you bear that name.*
Context
14Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín. 15Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. 16Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í, ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí. 17Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá, bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìyìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí? 18“Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,
níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò yọjú sí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.