Native Bible

1 Peter 4:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn.

1 Peter 4:15 in English

1 Peter 4:15 · Berean Standard Bible

Indeed, none of you should suffer as a murderer or thief or wrongdoer, or even as a meddler.

Context

13Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. 14Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín. 15Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. 16Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í, ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí. 17Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá, bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìyìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.