1 Peteru 2:18
1 Peter 2:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú.
1 Peter 2:18 in English
1 Peter 2:18 · Berean Standard Bible
Servants, submit yourselves to your masters with all respect,* not only to those who are good and gentle, but even to those who are unreasonable.
Context
16Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run. 17Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ́ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba. 18Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú. 19Nítorí pé èyí ní ìgbóríyìn fún, bí ènìyàn bá fi ara da ìrora, ìjìyà lọ́nà àìtọ́, nítorí ọkàn rere sí Ọlọ́run. 20Ṣùgbọ́n ògo kín ni ó jẹ́, nígbà tí ẹ ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á? Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá ń ṣe rere tí ẹ sì ń jìyà, bí ẹ bá fi sùúrù gbà á, ẹ̀yín ní ọpẹ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.