Native Bible

1 Peter 2:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run.

1 Peter 2:16 in English

1 Peter 2:16 · Berean Standard Bible

Live in freedom, but do not use your freedom as a cover-up for evil; live as servants of God.

Context

14Tàbí fún àwọn baálẹ̀, fún àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbẹ̀san lára àwọn tí ń ṣe búburú, àti fún ìyìn àwọn tí ń ṣe rere. 15Ìfẹ́ Ọlọ́run sá ni èyí pé, ní rere í ṣe, kí ẹ lè dẹ́kun ọ̀rọ̀ àìmọ̀kan òmùgọ̀ ènìyàn. 16Ẹ máa gbé gẹ́gẹ́ bí ẹni òmìnira, ṣùgbọ́n ẹ ma ṣe lo òmìnira yín láti bo ibi mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n kí ẹ gbé gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run. 17Ẹ bọ̀wọ̀ fún gbogbo ènìyàn, ẹ fẹ́ àwọn ará, ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ bọ̀wọ̀ fún ọba. 18Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọ̀gá yín pẹ̀lú ìbẹ̀rù gbogbo, kì í ṣe fún àwọn ẹni rere àti oníwà tútù nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn òǹrorò pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.