1 Peteru 1:4
1 Peter 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin,
1 Peter 1:4 in English
1 Peter 1:4 · Berean Standard Bible
and into an inheritance that is imperishable, undefiled, and unfading, reserved in heaven for you,
Context
2àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi:
Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín. 3Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, 4àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, 5ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. 6Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.