1 Peteru 1:24
1 Peter 1:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé, “Gbogbo ènìyàn dàbí koríko, àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko. Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,
1 Peter 1:24 in English
1 Peter 1:24 · Berean Standard Bible
For, “All flesh is like grass, and all its glory like the flowers of the field; the grass withers and the flowers fall,
Context
22Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. 24Nítorí pé,
“Gbogbo ènìyàn dàbí koríko,
àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.
Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù, 25ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”
Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìnrere tí a wàásù fún yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.