Native Bible

1 Kings 9:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀,

1 Kings 9:18 in English

1 Kings 9:18 · Berean Standard Bible

Baalath, and Tamar * in the Wilderness of Judah,*

Context

16Farao ọba Ejibiti sì ti kọlu Geseri, ó sì ti fi iná sun ún, ó sì pa àwọn ará Kenaani tí ń gbé ìlú náà, ó sì fi ta ọmọbìnrin rẹ̀, aya Solomoni lọ́rẹ. 17Solomoni sì tún Geseri kọ́, àti Beti-Horoni ìsàlẹ̀, 18àti Baalati àti Tadmori ní aginjù, láàrín rẹ̀, 19àti gbogbo ìlú ìṣúra tí Solomoni ní, àti ìlú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, àti ìlú fún àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀, àti èyí tí ó ń fẹ́ láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lebanoni àti ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ tí ó ń ṣe àkóso. 20Gbogbo ènìyàn tí ó kù nínú àwọn ará Amori ará Hiti, Peresi, Hifi àti Jebusi, àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ará Israẹli,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.