1 Ọba 8:9
1 Kings 8:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kò sí ohun kankan nínú àpótí ẹ̀rí bí kò ṣe wàláà òkúta méjì tí Mose ti fi sí ibẹ̀ ní Horebu, níbi tí Olúwa ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.
1 Kings 8:9 in English
1 Kings 8:9 · Berean Standard Bible
There was nothing in the ark except the two stone tablets that Moses had placed in it at Horeb,* where the LORD had made a covenant with the Israelites after they had come out of the land of Egypt.
Context
7Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e. 8Àwọn ọ̀pá yìí ga tó bẹ́ẹ̀ tí a fi le rí orí wọn láti Ibi Mímọ́ níwájú ibi tí a yà sí mímọ́, ṣùgbọ́n a kò sì rí wọn lóde Ibi Mímọ́, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. 9Kò sí ohun kankan nínú àpótí ẹ̀rí bí kò ṣe wàláà òkúta méjì tí Mose ti fi sí ibẹ̀ ní Horebu, níbi tí Olúwa ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti. 10Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti Ibi Mímọ́, àwọsánmọ̀ sì kún ilé Olúwa. 11Àwọn àlùfáà kò sì le ṣiṣẹ́ wọn nítorí àwọsánmọ̀ náà, nítorí ògo Olúwa kún ilé náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.