1 Ọba 8:7
1 Kings 8:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e.
1 Kings 8:7 in English
1 Kings 8:7 · Berean Standard Bible
For the cherubim spread their wings over the place of the ark and overshadowed the ark and its poles.
Context
5àti Solomoni ọba, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, wọ́n ń fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgùntàn àti màlúù tí a kò le mọ iye, àti tí a kò le kà rú ẹbọ. 6Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù. 7Àwọn kérúbù na ìyẹ́ wọn méjèèjì sí ibi àpótí ẹ̀rí, wọ́n sì bo àpótí ẹ̀rí náà, àti àwọn ọ̀pá rẹ̀ tí a fi ń gbé e. 8Àwọn ọ̀pá yìí ga tó bẹ́ẹ̀ tí a fi le rí orí wọn láti Ibi Mímọ́ níwájú ibi tí a yà sí mímọ́, ṣùgbọ́n a kò sì rí wọn lóde Ibi Mímọ́, wọ́n sì wà níbẹ̀ títí di òní yìí. 9Kò sí ohun kankan nínú àpótí ẹ̀rí bí kò ṣe wàláà òkúta méjì tí Mose ti fi sí ibẹ̀ ní Horebu, níbi tí Olúwa ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá májẹ̀mú, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.