Native Bible

1 Kings 8:63 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́.

1 Kings 8:63 in English

1 Kings 8:63 · Berean Standard Bible

And Solomon offered as peace offerings to the LORD 22,000 oxen and 120,000 sheep. So the king and all the Israelites dedicated the house of the LORD.

Context

61Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọkàn yín pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run wa, láti máa rìn nínú àṣẹ rẹ̀ àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, bí i ti òní yìí.” 62Nígbà náà ni ọba àti gbogbo Israẹli rú ẹbọ níwájú Olúwa. 63Solomoni rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa: ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) màlúù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) àgùntàn. Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ya ilé Olúwa sí mímọ́. 64Ní ọjọ́ kan náà ni ọba ya àgbàlá àárín tí ń bẹ níwájú ilé Olúwa sí mímọ́, níbẹ̀ ni ó sì rú ẹbọ sísun àti ọrẹ oúnjẹ, àti ẹbọ àlàáfíà, nítorí pẹpẹ idẹ tí ń bẹ níwájú Olúwa kéré jù láti gba ẹbọ sísun, àti ọrẹ oúnjẹ, àti ọrẹ ẹbọ àlàáfíà. 65Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe àpéjọ nígbà náà, àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hamati títí dé odò Ejibiti. Wọ́n sì ṣàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ọjọ́ méje àti ọjọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.