Native Bible

1 Kings 8:51 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Ejibiti jáde wá, láti inú irin ìléru.

1 Kings 8:51 in English

1 Kings 8:51 · Berean Standard Bible

For they are Your people and Your inheritance; You brought them out of Egypt, out of the furnace for iron.

Context

49nígbà náà ni kí ìwọ kí ó gbọ́ àdúrà wọn àti ẹ̀bẹ̀ wọn ní ọ̀run, ní ibùgbé rẹ, kí o sì mú ọ̀ràn wọn dúró. 50Kí o sì dáríjì àwọn ènìyàn rẹ, tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ; dárí gbogbo ìrékọjá wọn tí wọ́n ṣe sí ọ jì, kí o sì bá àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ wí, kí wọn kí ó lè ṣàánú fún wọn; 51nítorí ènìyàn rẹ àti ìní rẹ ni wọ́n, àwọn ẹni tí ìwọ ti mú ti Ejibiti jáde wá, láti inú irin ìléru. 52“Jẹ́ kí ojú rẹ ṣí sí ẹ̀bẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ, àti sí ẹ̀bẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ Israẹli, kí o sì tẹ́tí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá kégbe sí ọ. 53Nítorí tí ìwọ ti yà wọ́n kúrò nínú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, láti máa jẹ́ ìní rẹ, bí ìwọ ti sọ láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ, nígbà tí ìwọ Olúwa Olódùmarè, mú àwọn baba wa ti Ejibiti jáde wá.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.