1 Ọba 3:15
1 Kings 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Solomoni jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni. Ó sì padà sí Jerusalẹmu, ó sì dúró níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
1 Kings 3:15 in English
1 Kings 3:15 · Berean Standard Bible
Then Solomon awoke, and indeed it had been a dream. So he returned to Jerusalem, stood before the ark of the covenant of the Lord, and offered burnt offerings and peace offerings. Then he held a feast for all his servants.
Context
13Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. 14Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.” 15Solomoni jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.
Ó sì padà sí Jerusalẹmu, ó sì dúró níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 16Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbèrè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. 17Ọ̀kan nínú wọn sì wí pé, “Olúwa mi, èmi àti obìnrin yìí ń gbé nínú ilé kan. Èmi sì bí ọmọ ní ilé pẹ̀lú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.