1 Ọba 3:14
1 Kings 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”
1 Kings 3:14 in English
1 Kings 3:14 · Berean Standard Bible
So if you walk in My ways and keep My statutes and commandments, just as your father David did, I will prolong your days.”
Context
12èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ. 13Síwájú sí i, èmi yóò fi ohun tí ìwọ kò béèrè fún ọ: ọrọ̀ àti ọlá ní gbogbo ayé rẹ, tí kì yóò sí ẹnìkan nínú àwọn ọba tí yóò dàbí rẹ. 14Àti bí ìwọ bá rìn ní ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin àti àṣẹ mi mọ́ bí Dafidi baba rẹ ti ṣe, èmi yóò fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.” 15Solomoni jí: ó sì mọ̀ pé àlá ni.
Ó sì padà sí Jerusalẹmu, ó sì dúró níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà. Nígbà náà ni ó ṣe àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 16Lẹ́yìn náà ni àwọn obìnrin alágbèrè méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.