Native Bible

1 Kings 20:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko tètè kọ́ jáde lọ. Beni-Hadadi sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Àwọn ọkùnrin ń ti Samaria jáde wá.”

1 Kings 20:17 in English

1 Kings 20:17 · Berean Standard Bible

And the young officers of the district governors marched out first. Now Ben-hadad had sent out scouts, who reported to him, “Men are marching out of Samaria.”

Context

15Nígbà náà ni Ahabu ka àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232). Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tókù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000). 16Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Beni-Hadadi àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmupara nínú àgọ́. 17Àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko tètè kọ́ jáde lọ. Beni-Hadadi sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Àwọn ọkùnrin ń ti Samaria jáde wá.” 18Ó sì wí pé, “Bí wọ́n bá bá ti àlàáfíà jáde wá, ẹ mú wọn láààyè; bí ti ogun ni wọ́n bá bá jáde, ẹ mú wọn láààyè.” 19Àwọn ìjòyè kéékèèké wọ̀nyí ti àwọn ìjòyè ìgbèríko jáde ti ìlú wá, àti ogun tí ó tẹ̀lé wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.