1 Ọba 20:16
1 Kings 20:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Beni-Hadadi àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmupara nínú àgọ́.
1 Kings 20:16 in English
1 Kings 20:16 · Berean Standard Bible
They marched out at noon while Ben-hadad and the 32 kings allied with him were in their tents getting drunk.
Context
14Ahabu sì béèrè pé, “Ṣùgbọ́n ta ni yóò ṣe èyí?”
Wòlíì náà sì dáhùn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Nípa ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ àwọn ìjòyè ìgbèríko.’ ”
Nígbà náà ni ó wí pé. “Ta ni yóò bẹ̀rẹ̀ ogun náà?”
Wòlíì sì dalóhùn pé, “Ìwọ ni yóò ṣe é.” 15Nígbà náà ni Ahabu ka àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko, wọ́n sì jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232). Nígbà náà ni ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tókù jọ, gbogbo wọn sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000). 16Wọ́n sì jáde lọ ní ọ̀sán gangan, nígbà tí Beni-Hadadi àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tí ń ràn án lọ́wọ́ ń mu àmupara nínú àgọ́. 17Àwọn ìjòyè kéékèèké ìgbèríko tètè kọ́ jáde lọ.
Beni-Hadadi sì ránṣẹ́ jáde, wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Àwọn ọkùnrin ń ti Samaria jáde wá.” 18Ó sì wí pé, “Bí wọ́n bá bá ti àlàáfíà jáde wá, ẹ mú wọn láààyè; bí ti ogun ni wọ́n bá bá jáde, ẹ mú wọn láààyè.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.