Native Bible

1 Kings 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi Olúwa búra fún un pé, ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’

1 Kings 2:8 in English

1 Kings 2:8 · Berean Standard Bible

Keep an eye on Shimei the son of Gera, the Benjamite from Bahurim who is with you. He called down bitter curses against me on the day I went to Mahanaim, but when he came down to meet me at the Jordan, I swore to him by the LORD: ‘I will never put you to the sword.’

Context

6Ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú ní àlàáfíà. 7“Ṣùgbọ́n fi inú rere hàn sí àwọn ọmọ Barsillai, ti Gileadi, jẹ́ kí wọn wà lára àwọn tí ó ń jẹun lórí tábìlì rẹ̀. Wọ́n dúró tì mí nígbà tí mo sá kúrò níwájú Absalomu arákùnrin rẹ. 8“Àti kí o rántí, Ṣimei ọmọ Gera ẹ̀yà Benjamini tí Bahurimu wà pẹ̀lú rẹ̀, tí ó bú mi ní èébú tí ó korò ní ọjọ́ tí mo lọ sí Mahanaimu. Nígbà tí ó sọ̀kalẹ̀ wá pàdé mi ní Jordani, mo fi Olúwa búra fún un pé, ‘Èmi kì yóò fi idà pa ọ́.’ 9Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, má ṣe kíyèsi í gẹ́gẹ́ bí aláìlẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n ni ìwọ ṣe; ìwọ yóò mọ ohun tí ìwọ yóò ṣe sí i. Mú ewú orí rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sínú isà òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.” 10Nígbà náà ni Dafidi sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.