1 Ọba 2:40
1 Kings 2:40 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati.
1 Kings 2:40 in English
1 Kings 2:40 · Berean Standard Bible
So Shimei saddled his donkey and set out to Achish at Gath in search of his slaves, and he brought them back from Gath.
Context
38Ṣimei sì dá ọba lóhùn pé, “Ohun tí ìwọ sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe bí olúwa mi ọba ti wí.” Ṣimei sì gbé ní Jerusalẹmu fún ìgbà pípẹ́. 39Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ Ṣimei méjì sì sálọ sọ́dọ̀ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati, a sì sọ fún Ṣimei pé, “Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ méjì wà ní Gati.” 40Fún ìdí èyí, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì lọ sọ́dọ̀ Akiṣi ní Gati láti wá àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ṣimei sì lọ, ó sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ padà bọ̀ láti Gati. 41Nígbà tí a sì sọ fún Solomoni pé Ṣimei ti lọ láti Jerusalẹmu sí Gati, ó sì ti padà. 42Ọba pe Ṣimei lẹ́jọ́, ó wí fún un pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ti mú ọ búra ní ti Olúwa, èmi sì ti kìlọ̀ fún ọ pé, ‘Ní ọjọ́ tí ìwọ bá kúrò láti lọ sí ibikíbi, kí o mọ̀ dájú pé ìwọ yóò kú.’ Nígbà náà ni ìwọ sì sọ fún mi pé, ‘Ohun tí ìwọ sọ dára. Èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.