1 Ọba 2:27
1 Kings 2:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ.
1 Kings 2:27 in English
1 Kings 2:27 · Berean Standard Bible
So Solomon banished Abiathar from the priesthood of the LORD and thus fulfilled the word that the LORD had spoken at Shiloh against the house of Eli.
Context
25Solomoni ọba sì pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada, ó sì kọlu Adonijah, ó sì kú. 26Ọba sì wí fún Abiatari àlùfáà pé, “Padà lọ sí pápá rẹ ni Anatoti, ó yẹ fún ọ láti kú, ṣùgbọ́n èmi kì yóò pa ọ́ nísinsin yìí, nítorí o ti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa Olódùmarè níwájú Dafidi baba mi, o sì ti ní ìpín nínú gbogbo ìyà tí baba mi jẹ.” 27Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni yọ Abiatari kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà Olúwa, kí ó lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípa ilé Eli ní Ṣilo ṣẹ. 28Nígbà tí ìròyìn sì dé ọ̀dọ̀ Joabu, ẹni tí ó ti dìtẹ̀ pẹ̀lú Adonijah bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò wà pẹ̀lú Absalomu, ó sì sálọ sínú àgọ́ Olúwa, ó sì di ìwo pẹpẹ mú. 29A sì sọ fún Solomoni ọba pé Joabu ti sálọ sínú àgọ́ Olúwa àti pé ó wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. Nígbà náà ni Solomoni pàṣẹ fún Benaiah ọmọ Jehoiada pé, “Lọ, kí o sì kọlù ú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.