Native Bible

1 Kings 2:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi.

1 Kings 2:12 in English

1 Kings 2:12 · Berean Standard Bible

So Solomon sat on the throne of his father David, and his kingdom was firmly established.

Context

10Nígbà náà ni Dafidi sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi. 11Dafidi ti jẹ ọba lórí Israẹli ní ogójì ọdún, ọdún méje ni Hebroni àti ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ní Jerusalẹmu. 12Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀, ìjọba rẹ̀ sì fi ìdí múlẹ̀ gidigidi. 13Wàyí, Adonijah ọmọ Haggiti tọ Batṣeba, ìyá Solomoni wá. Batṣeba sì bi í pé, “Àlàáfíà ni o bá wa bí?” Ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà ni.” 14Nígbà náà ni ó sì fi kún un pé, “Mo ní ohun kan láti sọ fún ọ.” Batṣeba sì wí pé, “Máa wí.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.