Native Bible

1 Kings 19:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀.

1 Kings 19:9 in English

1 Kings 19:9 · Berean Standard Bible

There Elijah entered a cave and spent the night. And the word of the LORD came to him, saying, “What are you doing here, Elijah?”

Context

7Angẹli Olúwa sì tún padà wá lẹ́ẹ̀kejì, ó sì tún fi ọwọ́ tọ́ ọ, ó sì wí pé, “Dìde, kí ó jẹun, nítorí ìrìnàjò náà jì fún ọ.” 8Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run. 9Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀. 10(9) Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?” (10) Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.” 11Olúwa sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa, nítorí Olúwa fẹ́ rékọjá.” Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú Olúwa; ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.