1 Ọba 19:20
1 Kings 19:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Eliṣa sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì sáré tọ Elijah lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” Elijah sì dáhùn wí pé, “Padà sẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́?”
1 Kings 19:20 in English
1 Kings 19:20 · Berean Standard Bible
So Elisha left the oxen, ran after Elijah, and said, “Please let me kiss my father and mother goodbye, and then I will follow you.” “Go on back,” Elijah replied, “for what have I done to you?”
Context
18Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.” 19Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Eliṣa ọmọ Ṣafati. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú èkejìlá. Elijah sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó. 20Nígbà náà ni Eliṣa sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì sáré tọ Elijah lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”
Elijah sì dáhùn wí pé, “Padà sẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́?” 21Eliṣa sì fi í sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Elijah lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.