1 Ọba 14:3
1 Kings 14:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.”
1 Kings 14:3 in English
1 Kings 14:3 · Berean Standard Bible
Take with you ten loaves of bread, some cakes, and a jar of honey, and go to him. He will tell you what will become of the boy.”
Context
1Ní àkókò náà Abijah ọmọ Jeroboamu sì ṣàìsàn, 2Jeroboamu sì wí fún aya rẹ̀ pé, “Lọ, sì pa ara rẹ dà, kí wọn kí ó má ba à mọ̀ ọ́n ní aya Jeroboamu. Nígbà náà ni kí o lọ sí Ṣilo. Ahijah wòlíì wà níbẹ̀; ẹni tí ó sọ fún mi pé, èmi yóò jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn yìí. 3Mú ìṣù àkàrà mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, àti àkàrà wẹ́wẹ́ àti ìgò oyin, kí o sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Òun yóò sì sọ fún ọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ọmọkùnrin náà.” 4Bẹ́ẹ̀ ni aya Jeroboamu sì ṣe bí ó ti wí, ó sì lọ sí ilé Ahijah ní Ṣilo.
Ahijah kò sì ríran; ojú rẹ̀ ti fọ́ nítorí ogbó rẹ̀. 5Ṣùgbọ́n Olúwa ti sọ fún Ahijah pé, “Kíyèsi i, aya Jeroboamu ń bọ̀ wá béèrè nípa ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ, nítorí tí ó ṣàìsàn, báyìí báyìí ni kí ìwọ kí ó wí fún un. Nígbà tí ó bá dé, yóò ṣe ara rẹ̀ bí ẹlòmíràn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.