Native Bible

1 Kings 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí àmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

1 Kings 13:5 in English

1 Kings 13:5 · Berean Standard Bible

And the altar was split apart, and the ashes poured out, according to the sign that the man of God had given by the word of the LORD.

Context

3Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní àmì kan wí pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.” 4Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un!” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́. 5Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí àmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa. 6Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀. 7Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.