1 Ọba 13:3
1 Kings 13:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní àmì kan wí pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”
1 Kings 13:3 in English
1 Kings 13:3 · Berean Standard Bible
That day the man of God gave a sign, saying, “The LORD has spoken this sign: ‘Surely the altar will be split apart, and the ashes upon it will be poured out.’”
Context
1Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná. 2Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ” 3Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní àmì kan wí pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.” 4Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un!” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́. 5Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí àmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.