Native Bible

1 Kings 12:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Rehoboamu sì dé sí Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ilé Juda jọ, àti ẹ̀yà Benjamini; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Israẹli jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.

1 Kings 12:21 in English

1 Kings 12:21 · Berean Standard Bible

And when Rehoboam arrived in Jerusalem, he mobilized the whole house of Judah and the tribe of Benjamin—180,000 chosen warriors—to fight against the house of Israel and restore the kingdom to Rehoboam son of Solomon.

Context

19Bẹ́ẹ̀ ni Israẹli ṣọ̀tẹ̀ sí ilé Dafidi títí di òní yìí. 20Nígbà tí gbogbo Israẹli sì gbọ́ pé Jeroboamu ti padà dé, wọ́n ránṣẹ́, wọ́n sì pè é wá sí àjọ, wọ́n sì fi jẹ ọba lórí gbogbo Israẹli. Kò sí ẹnìkan tí ó tọ ilé Dafidi lẹ́yìn bí kò ṣe kìkì ẹ̀yà Juda nìkan. 21Nígbà tí Rehoboamu sì dé sí Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ilé Juda jọ, àti ẹ̀yà Benjamini; ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n ń ṣe ológun, láti bá ilé Israẹli jà àti láti mú ìjọba náà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Rehoboamu, ọmọ Solomoni. 22Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Ṣemaiah ènìyàn Ọlọ́run wá wí pé, 23“Sọ fún Rehoboamu, ọmọ Solomoni, ọba Juda àti fún gbogbo ilé Juda àti ti Benjamini, àti fún àwọn ènìyàn tókù wí pé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.