Native Bible

1 Kings 11:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Hadadi sálọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ará Edomu tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ baba rẹ̀. Hadadi sì wà ní ọmọdé nígbà náà.

1 Kings 11:17 in English

1 Kings 11:17 · Berean Standard Bible

But Hadad, still just a young boy, had fled to Egypt, along with some Edomites who were servants of his father.

Context

15Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi wà ní Edomu, Joabu olórí ogun sì gòkè lọ láti sin àwọn ọmọ-ogun Israẹli ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Edomu. 16Nítorí Joabu àti gbogbo Israẹli sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, títí wọ́n fi pa gbogbo ọkùnrin Edomu run. 17Ṣùgbọ́n Hadadi sálọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ará Edomu tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ baba rẹ̀. Hadadi sì wà ní ọmọdé nígbà náà. 18Wọ́n sì dìde kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Nígbà náà ni wọ́n mú ènìyàn pẹ̀lú wọn láti Parani wá, wọ́n sì lọ sí Ejibiti, sọ́dọ̀ Farao ọba Ejibiti ẹni tí ó fún Hadadi ní ilé àti ilẹ̀, ó sì fún un ní oúnjẹ. 19Inú Farao sì dùn sí Hadadi púpọ̀ tí ó fi fún un ní arábìnrin aya rẹ̀ ní aya, arábìnrin Tapenesi, ayaba.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.