1 Ọba 11:15
1 Kings 11:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi wà ní Edomu, Joabu olórí ogun sì gòkè lọ láti sin àwọn ọmọ-ogun Israẹli ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Edomu.
1 Kings 11:15 in English
1 Kings 11:15 · Berean Standard Bible
Earlier, when David was in Edom, Joab the commander of the army had gone to bury the dead and had struck down every male in Edom.
Context
13Síbẹ̀ èmi kì yóò fa gbogbo ìjọba náà ya, ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀yà kan fún ọmọ rẹ nítorí Dafidi ìránṣẹ́ mi, àti nítorí Jerusalẹmu tí èmi ti yàn.” 14Nígbà náà ni Olúwa gbé ọ̀tá kan dìde sí Solomoni, Hadadi ará Edomu ìdílé ọba ni ó ti wá ní Edomu. 15Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi wà ní Edomu, Joabu olórí ogun sì gòkè lọ láti sin àwọn ọmọ-ogun Israẹli ti a pa lójú ogun, ó sì pa gbogbo ọkùnrin Edomu. 16Nítorí Joabu àti gbogbo Israẹli sì dúró níbẹ̀ fún oṣù mẹ́fà, títí wọ́n fi pa gbogbo ọkùnrin Edomu run. 17Ṣùgbọ́n Hadadi sálọ sí Ejibiti pẹ̀lú àwọn ará Edomu tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ baba rẹ̀. Hadadi sì wà ní ọmọdé nígbà náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.