1 Ọba 10:13
1 Kings 10:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Solomoni ọba sì fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Solomoni ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
1 Kings 10:13 in English
1 Kings 10:13 · Berean Standard Bible
King Solomon gave the queen of Sheba all she desired—whatever she asked—besides what he had given her out of his royal bounty. Then she left and returned to her own country, along with her servants.
Context
11(Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hiramu tí ó mú wúrà láti Ofiri wá, wọ́n mú igi algumu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ àti òkúta oníyebíye láti Ofiri wá. 12Ọba sì fi igi algumu náà ṣe òpó fún ilé Olúwa àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Irú igi algumu bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí.) 13Solomoni ọba sì fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Solomoni ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. 14Ìwọ̀n wúrà tí Solomoni ń gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666) tálẹ́ǹtì wúrà, 15láìka èyí tí ó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ajẹ́lẹ̀ àti àwọn oníṣòwò, àti ti gbogbo àwọn ọba Arabia, àti àwọn baálẹ̀ ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.