1 Ọba 10:11
1 Kings 10:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
(Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hiramu tí ó mú wúrà láti Ofiri wá, wọ́n mú igi algumu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ àti òkúta oníyebíye láti Ofiri wá.
1 Kings 10:11 in English
1 Kings 10:11 · Berean Standard Bible
(The fleet of Hiram that brought gold from Ophir also brought from Ophir a great cargo of almug * wood and precious stones.
Context
9Ìbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó ní inú dídùn sí ọ, tí ó sì gbé ọ ka orí ìtẹ́ Israẹli. Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn Israẹli títí láé, ni ó ṣe fi ọ́ jẹ ọba, láti ṣe ìdájọ́ àti òdodo.” 10Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà, tùràrí olóòórùn dídùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dàbí irú èyí tí ayaba Ṣeba fi fún Solomoni ọba. 11(Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hiramu tí ó mú wúrà láti Ofiri wá, wọ́n mú igi algumu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ àti òkúta oníyebíye láti Ofiri wá. 12Ọba sì fi igi algumu náà ṣe òpó fún ilé Olúwa àti fún ààfin ọba, àti láti ṣe dùùrù pẹ̀lú àti ohun èlò orin olókùn fún àwọn akọrin. Irú igi algumu bẹ́ẹ̀ kò dé mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí wọn títí di òní yìí.) 13Solomoni ọba sì fún ayaba Ṣeba ní gbogbo ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tí ó béèrè, yàtọ̀ sí èyí tí a fi fún un láti ọwọ́ Solomoni ọba wa. Nígbà náà ni ó yípadà, ó sì lọ sí ìlú rẹ̀, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.