1 Johanu 4:3
1 John 4:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run, èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.
1 John 4:3 in English
1 John 4:3 · Berean Standard Bible
and every spirit that does not confess Jesus * is not from God. This is the spirit of the antichrist, which you have heard is coming and which is already in the world at this time.
Context
1Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run, nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé. 2Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run. Gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni. 3Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run, èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé. 4Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn, nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ. 5Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.