Native Bible

1 John 4:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run, nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé.

1 John 4:1 in English

1 John 4:1 · Berean Standard Bible

Beloved, do not believe every spirit, but test the spirits to see whether they are from God. For many false prophets have gone out into the world.

Context

1Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run, nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé. 2Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run. Gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni. 3Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run, èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.