Native Bible

1 John 4:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwa tí rí, a sì jẹ́rìí pé Baba rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà fún aráyé.

1 John 4:14 in English

1 John 4:14 · Berean Standard Bible

And we have seen and testify that the Father has sent His Son to be the Savior of the world.

Context

12Ẹnikẹ́ni kò ri Ọlọ́run nígbà kan rí. Bí àwa bá fẹ́ràn ara wa, Ọlọ́run ń gbé inú wa, a sì mú ìfẹ́ rẹ̀ pé nínú wa. 13Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń gbé inú rẹ̀, àti Òun nínú wa, nítorí tí ó ti fi Ẹ̀mí rẹ̀ fún wa. 14Àwa tí rí, a sì jẹ́rìí pé Baba rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà fún aráyé. 15Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu Ọmọ Ọlọ́run ni, Ọlọ́run ń gbé inú rẹ̀, àti òun nínú Ọlọ́run. 16Báyìí ni àwa mọ̀, tí a sì gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run; ẹni tí ó bá sì ń gbé inú ìfẹ́, ó ń gbé inú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.