Native Bible

1 John 2:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀.

1 John 2:5 in English

1 John 2:5 · Berean Standard Bible

But if anyone keeps His word, the love of God has been truly perfected in him. By this we know that we are in Him:

Context

3Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. 4Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. 5Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. 6Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn. 7Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.