1 Johanu 2:15
1 John 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀.
1 John 2:15 in English
1 John 2:15 · Berean Standard Bible
Do not love the world or anything in the world. If anyone loves the world, the love of the Father is not in him.
Context
13Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,
nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe,
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,
nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà. 14Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n,
nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,
nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètèkọ́ṣe.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,
nítorí tí ẹ̀yin ni agbára,
tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín,
tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà. 15Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀. 16Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé. 17Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.