1 Kọrinti 9:19
1 Corinthians 9:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i.
1 Corinthians 9:19 in English
1 Corinthians 9:19 · Berean Standard Bible
Though I am free of obligation to anyone, I make myself a slave to everyone, to win as many as possible.
Context
17Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. 18Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìyìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni. 19Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìyìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.