Native Bible

1 Corinthians 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.

1 Corinthians 8:6 in English

1 Corinthians 8:6 · Berean Standard Bible

yet for us there is but one God, the Father, from whom all things came and for whom we exist. And there is but one Lord, Jesus Christ, through whom all things came and through whom we exist.

Context

4Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láìṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ní ń bẹ, kò sì ṣí ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo. 5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). 6Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀. 7Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́. 8Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.