Native Bible

1 Corinthians 7:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn.

1 Corinthians 7:23 in English

1 Corinthians 7:23 · Berean Standard Bible

You were bought at a price; do not become slaves of men.

Context

21Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì. 22Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi. 23A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn. 24Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run. 25Ṣùgbọ́n nípa ti àwọn wúńdíá, èmi kò ní àṣẹ kankan láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n mo wí fún yín ní ìdájọ́ bí ẹni tí ó rí àánú Olúwa gbà láti jẹ́ olódodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.