Native Bible

1 Corinthians 7:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe le mọ̀ pé bóyá ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ.

1 Corinthians 7:16 in English

1 Corinthians 7:16 · Berean Standard Bible

How do you know, wife, whether you will save your husband? Or how do you know, husband, whether you will save your wife?

Context

14Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́. 15Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Arákùnrin tàbí arábìnrin náà kò sí lábẹ́ ìdè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlàáfíà. 16Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe le mọ̀ pé bóyá ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ. 17Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí. Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyí. 18Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó má sì ṣe di aláìkọlà. Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó ma ṣe kọlà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.