Native Bible

1 Corinthians 6:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.

1 Corinthians 6:10 in English

1 Corinthians 6:10 · Berean Standard Bible

nor thieves, nor the greedy, nor drunkards, nor verbal abusers, nor swindlers, will inherit the kingdom of God.

Context

8Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. 9Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ 10tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. 11Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa. 12“Ohun gbogbo ní ó tọ́ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe olórí fun mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.