Native Bible

1 Corinthians 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá.

1 Corinthians 3:6 in English

1 Corinthians 3:6 · Berean Standard Bible

I planted the seed and Apollos watered it, but God made it grow.

Context

4Ǹjẹ́ ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn lásán bí? Níwọ́n ìgbà tí ẹ ba ń sọ pé, “Èmi ń tẹ̀lé Paulu,” àti ti ẹlòmíràn tún wí pé, “Èmi ń tẹ̀lé Apollo.” 5Jú gbogbo rẹ̀ lọ, kí ni Apollo ha jẹ́, kín ni Paulu sì jẹ́, àwọn ìránṣẹ́ lásán, nípasẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti fi fún olúkúlùkù. 6Èmi gbìn, Apollo ń bomirin; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni ń mú ìbísí wá. 7Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹni tí ó ń gbìn nǹkan kan, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹni tí ń bomirin; bí kò ṣe Ọlọ́run tí ó ń mú ìbísí wá. 8Ẹni tí ó ń gbìn àti ẹni tí ó ń bu omi rín ní ìrònú kan àti èrèdí kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yóò gba èrè tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe é kárakára tó.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.