1 Kọrinti 2:15
1 Corinthians 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.
1 Corinthians 2:15 in English
1 Corinthians 2:15 · Berean Standard Bible
The spiritual man judges all things, but he himself is not subject to anyone’s judgment.
Context
13Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 14Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọn-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀. 16“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,
ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”
Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.