1 Kọrinti 15:46
1 Corinthians 15:46 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí.
1 Corinthians 15:46 in English
1 Corinthians 15:46 · Berean Standard Bible
The spiritual, however, was not first, but the natural, and then the spiritual.
Context
44A gbìn ín ni, ara ẹran a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.
Bí ara ẹran bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ. 45Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a”; Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè. 46Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí. 47Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni. 48Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.