1 Kọrinti 15:39
1 Corinthians 15:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ.
1 Corinthians 15:39 in English
1 Corinthians 15:39 · Berean Standard Bible
Not all flesh is the same: Men have one kind of flesh, animals have another, birds another, and fish another.
Context
37àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n èso lásán ni, ìbá à ṣe alikama, tàbí irú mìíràn. 38Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irúgbìn ara tirẹ̀. 39Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà, ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ. 40Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ, ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀. 41Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.