1 Kọrinti 12:30
1 Corinthians 12:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí?
1 Corinthians 12:30 in English
1 Corinthians 12:30 · Berean Standard Bible
Do all have gifts of healing? Do all speak in tongues? Do all interpret?
Context
28Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí? 31Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.
Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.