1 Kọrinti 12:28
1 Corinthians 12:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè.
1 Corinthians 12:28 in English
1 Corinthians 12:28 · Berean Standard Bible
And in the church God has appointed first of all apostles, second prophets, third teachers, then workers of miracles, and those with gifts of healing, helping, administration, and various tongues.
Context
26Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀. 27Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi. 28Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.