1 Kọrinti 12:25
1 Corinthians 12:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn.
1 Corinthians 12:25 in English
1 Corinthians 12:25 · Berean Standard Bible
so that there should be no division in the body, but that its members should have mutual concern for one another.
Context
23Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ. 24Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní. 25Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. 26Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀. 27Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.