1 Kọrinti 12:24
1 Corinthians 12:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní.
1 Corinthians 12:24 in English
1 Corinthians 12:24 · Berean Standard Bible
whereas our presentable parts have no such need. But God has composed the body and has given greater honor to the parts that lacked it,
Context
22Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan an ni a kò le ṣe aláìnílò. 23Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ. 24Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní. 25Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. 26Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.