Native Bible

1 Corinthians 11:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe.

1 Corinthians 11:7 in English

1 Corinthians 11:7 · Berean Standard Bible

A man ought not to cover his head, since he is the image and glory of God; but the woman is the glory of man.

Context

5Bẹ́ẹ̀ náà ni obìnrin tí ó bá ń gbàdúrà tàbí tí ó bá ń sọtẹ́lẹ̀ láìbo orí rẹ̀, kò bu ọlá fún orí ara rẹ̀ nítorí ọ̀kan náà ni pẹ̀lú ẹni tí ó fárí. 6Ṣùgbọ́n tí obìnrin bá kọ̀ láti bo orí rẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó gé irun rẹ̀. Bí ó bá sì jẹ́ nǹkan ìtìjú fún un láti gé irun orí rẹ́, nígbà náà kí ó fi gèlè bo orí rẹ̀. 7Ṣùgbọ́n ọkùnrin kò ní láti fi nǹkan bo orí rẹ́ nígbà tí ó bá ń sìn, nítorí àwòrán àti ògo Ọlọ́run ni òun í ṣe, ṣùgbọ́n ògo ọkùnrin ni obìnrin í ṣe. 8Ọkùnrin kò ti inú obìnrin wá, ṣùgbọ́n a yọ obìnrin jáde lára ọkùnrin, 9bẹ́ẹ̀ ni a kò dá ọkùnrin fún àǹfààní obìnrin ṣùgbọ́n a da obìnrin fún ọkùnrin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.