Native Bible

1 Corinthians 10:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.”

1 Corinthians 10:7 in English

1 Corinthians 10:7 · Berean Standard Bible

Do not be idolaters, as some of them were. As it is written: “The people sat down to eat and to drink, and got up to indulge in revelry.”*

Context

5Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù. 6Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” 8Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹgbẹ̀rún (23,000) ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. 9Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.