Native Bible

1 Corinthians 10:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.

1 Corinthians 10:5 in English

1 Corinthians 10:5 · Berean Standard Bible

Nevertheless, God was not pleased with most of them, for they were struck down in the wilderness.

Context

3Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. 4Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. 5Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù. 6Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.